+ -

عن ابن عباس رضي الله عنهما
عَنِ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ فِيمَا يَرْوِي عَنْ رَبِّهِ عَزَّ وَجَلَّ قَالَ: قَالَ: «إِنَّ اللهَ كَتَبَ الْحَسَنَاتِ وَالسَّيِّئَاتِ، ثُمَّ بَيَّنَ ذَلِكَ، فَمَنْ هَمَّ بِحَسَنَةٍ فَلَمْ يَعْمَلْهَا كَتَبَهَا اللهُ لَهُ عِنْدَهُ حَسَنَةً كَامِلَةً، فَإِنْ هُوَ هَمَّ بِهَا فَعَمِلَهَا كَتَبَهَا اللهُ لَهُ عِنْدَهُ عَشْرَ حَسَنَاتٍ إِلَى سَبْعِمِائَةِ ضِعْفٍ، إِلَى أَضْعَافٍ كَثِيرَةٍ، وَمَنْ هَمَّ بِسَيِّئَةٍ فَلَمْ يَعْمَلْهَا كَتَبَهَا اللهُ لَهُ عِنْدَهُ حَسَنَةً كَامِلَةً، فَإِنْ هُوَ هَمَّ بِهَا فَعَمِلَهَا كَتَبَهَا اللهُ لَهُ سَيِّئَةً وَاحِدَةً».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 6491]
المزيــد ...

Lati ọdọ Ibnu Abbaas (ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji)
Lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ninu nǹkan ti o gba wa lati ọdọ Oluwa rẹ ti O lágbára ti O gbọnngbọn, o sọ pé: “Dájúdájú Ọlọhun kọ daadaa ati aburu, lẹyin naa O ṣalaye ìyẹn, ẹni tí ó bá gbèrò dáadáa, ti ko wa ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni ọdọ Rẹ ni dáadáa ti o pé, ti o ba wa gbero rẹ, ti o wa ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni ọdọ Rẹ ni dáadáa mẹ́wàá titi de ìlọ́po ẹẹdẹgbẹrin, titi de ìlọ́po ti o pọ̀, ẹni ti o ba gbèrò aburu, ti ko wa ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni ọdọ Rẹ ni dáadáa ti o pe, ti o ba wa gbero rẹ ti o si ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni aburu ẹyọkan”.

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 6491]

Àlàyé

Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe Ọlọhun ti kádàrá dáadáa ati aburú, lẹyin naa O ṣàlàyé fun awọn malaika méjèèjì bi wọn ṣe maa kọ ọ:
Ẹni tí ó bá gbèrò ṣíṣe dáadáa, wọn maa kọ ọ fun un ni dáadáa ẹyọkan koda ki o ma ṣe e, ti o ba wa ṣe e, wọn maa ṣe adipele rẹ pẹlu ìlọ́po mẹ́wàá irú rẹ titi de ìlọ́po ẹẹdẹgbẹrin, titi de ìlọ́po ti o pọ, alekun naa maa wa ni ibamu si bi ọkàn ba ṣe ni imọkanga sí, ati bi àwọn èèyàn ba ṣe ṣe anfaani latara rẹ̀ si, ati ohun ti o jọ ìyẹn.
Ẹni tí ó bá gbèrò lati ṣe aburu, lẹyin naa o wa gbe e ju silẹ, wọn maa kọ ọ fun ni dáadáa, ti ko ba wa raye ṣe e pẹlu pe ko ṣe àwọn okunfa rẹ, wọn ko nii kọ nǹkan kan, ti o ba gbe e ju silẹ ni ti ikagara, wọn maa kọ àníyàn rẹ fun un, ti o ba wa ṣe e, wọn maa kọ ọ fun un ni aburu ẹyọkan.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè Fulani Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف البلغارية Ti ede Azerbaijan Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية اللينجالا المقدونية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣiṣe àlàyé ọla Ọlọhun ti o tobi lori ijọ yii nibi adipele àwọn dáadáa ati kikọ wọn ni ọdọ Rẹ, ati àìsí adipele fun aburu.
  2. Pataki aniyan ninu awọn iṣẹ ati oripa rẹ.
  3. Ọlá Ọlọhun ati aanu Rẹ ati dáadáa Rẹ ni pe ẹni ti o ba gbèrò dáadáa ti ko wa ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ ni dáadáa.