+ -

عن شداد بن أوس رضي الله عنه قال: ثِنْتَانِ حَفِظْتُهُمَا عَنْ رَسُولِ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«إِنَّ اللهَ كَتَبَ الْإِحْسَانَ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ، فَإِذَا قَتَلْتُمْ فَأَحْسِنُوا الْقِتْلَةَ، وَإِذَا ذَبَحْتُمْ فَأَحْسِنُوا الذَّبْحَ، وَلْيُحِدَّ أَحَدُكُمْ شَفْرَتَهُ، فَلْيُرِحْ ذَبِيحَتَهُ».

[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 1955]
المزيــد ...

Lati ọdọ Shaddaad ọmọ Aos- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo há nǹkan méjì lẹ́nu ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o sọ pe:
“Dájúdájú Ọlọhun ti ṣe dáadáa ni ọranyan nibi gbogbo nǹkan, ti ẹ ba ti fẹ pa nǹkan ki ẹ pa a dáadáa, ti ẹ ba ti fẹ du nǹkan, ki ẹ du u dáadáa, ki ẹni kọọkan yin pọ́n ọ̀bẹ rẹ ki ó mú, ki o si tètè ko ìsinmi ba nǹkan ti o fẹ dú”.

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 1955]

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ṣe daadaa ni ọranyan le wa lori nibi gbogbo nǹkan. Dáadáa ni: Ìpayà Ọlọhun ni gbogbo ìgbà, níbi ìjọsìn fun Un, ati ṣíṣe oore, ati ki èèyàn má ṣe àwọn ẹ̀dá ni suta, ninu ìyẹn naa ni ṣíṣe dáadáa nibi pípa ati didu.
Ṣíṣe dáadáa nibi pipa nigba ti a ba fẹ gba ẹsan: Pẹ̀lú sisẹṣa ọna ti o rọrun ju ti o si yára ju lati gba ẹ̀mí ẹni ti a fẹ pa.
Ṣíṣe dáadáa nibi dídú nígbà tí a ba n dú nǹkan: Pẹ̀lú ṣíṣe pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú ẹran-ọ̀sìn pẹlu pípọ́n irinṣẹ naa, ki a si ma pọ́n ọn ni iwájú nǹkan ti a fẹ du ti o si n wò ó, ki a si ma dú u ni ibi tí ẹran-ọ̀sìn mìíràn wa ti o n wò ó.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè Fulani Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف البلغارية Ti ede Azerbaijan Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية اللينجالا المقدونية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Àánú Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn si ẹ̀dá.
  2. Pipa ati didu nǹkan dáadáa pẹ̀lú ki o jẹ ọ̀nà ti o ba òfin mu.
  3. Pípé ṣẹria ati kiko ti o ko gbogbo oore sinu, ninu ìyẹn ni àánú ẹranko ati ṣíṣe pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú ẹ.
  4. Kíkọ̀ kúrò nibi ifi ìyà jẹ ènìyàn lẹ́yìn pípa a.
  5. Ṣiṣe gbogbo nnkan ti ìjìyà ba n bẹ nibẹ fun ẹranko ni eewọ.