+ -

عن تميم الداري رضي الله عنه أن النبي صلى الله عليه وسلم قال:
«الدِّينُ النَّصِيحَةُ» قُلْنَا: لِمَنْ؟ قَالَ: «لِلهِ وَلِكِتَابِهِ وَلِرَسُولِهِ وَلِأَئِمَّةِ الْمُسْلِمِينَ وَعَامَّتِهِمْ».

[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 55]
المزيــد ...

Lati ọdọ Tamiim Ad-Daariy- ki Ọlọhun yọnu si i- pe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe:
“Ẹsin ìmọ̀ràn ni”, a sọ pé: Fún tani? O sọ pe: “Fún Ọlọhun, ati fun tira Rẹ̀, ati fun ojiṣẹ Rẹ, ati fun awọn aṣiwaju Mùsùlùmí ati apapọ wọn”.

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 55]

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe ẹsin duro lori imọkanga ati ododo, titi ti eeyan fi maa pé e gẹ́gẹ́ bi Ọlọhun ṣe ṣe e ni dandan, ni pípé láìsí ikudiẹ-kaato nibẹ tabi irẹjẹ.
Wọn wa sọ fun Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pé: Ìmọ̀ràn fun tani? O sọ pe:
Akọkọ: Ìmọ̀ràn fun Ọlọhun ti ọla Rẹ ga: Pẹ̀lú mimọ iṣẹ kangá fun Un, ati ki èèyàn ma da orogun pọ̀ mọ́ Ọn, ki a si gbagbọ ninu ijẹ Oluwa Rẹ, ati ìní-ẹ̀tọ́ si ìjọsìn Rẹ, ati awọn orúkọ Rẹ ati awọn ìròyìn Rẹ, ati gbigbe ọ̀rọ̀ Rẹ tobi, ati ipepe lọ sibi ìní ìgbàgbọ́ si I.
Ìkejì: Ìmọ̀ràn fun tira Rẹ tii ṣe Kuraani Alapọn-ọnle: Pẹlu pe ki a ni adisọkan pe ọrọ Rẹ ni, oun si ni tira Rẹ ti o kẹyin, o si ti pa gbogbo àwọn ofin ti o ṣíwájú rẹ̀ rẹ́, a maa gbe e tobi, a si maa ka a bi o ṣe tọ́. A maa lo eyi ti ko ba rújú nínú ẹ, a si maa yọnu si èyí ti o ba rújú ninu ẹ, a si maa le àwọn èèyàn kuro nibi itukutuu àwọn ti n yi itumọ rẹ padà, a si maa woye si awọn wàásù rẹ, a si maa tan imọ rẹ ka, a si maa pepe si i.
Ìkẹta: Ìmọ̀ràn fun ojiṣẹ Rẹ tii ṣe Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-: Pẹ̀lú ki a ni adisọkan pe oun ni igbẹyin àwọn ojiṣẹ, ki a si gba a lododo nibi nǹkan ti o mu wa, ki a si tẹle àṣẹ rẹ, ki a si jinna si ohun ti o bá kọ̀. Ki a si ma jọ́sìn fun Ọlọhun àyàfi pẹ̀lú nǹkan ti o mu wa, ki a si maa gbe iwọ̀ rẹ tobi, ki a si maa pọn ọn le, ki a si maa tan ipepe rẹ ká, ki a si maa fọn ofin rẹ ka, ki a si maa tako àwọn ẹ̀sùn ti wọn ba fi kan an.
Ikẹrin: Ìmọ̀ràn fun awọn aṣiwaju àwọn mùsùlùmí: Pẹ̀lú riran wọn lọ́wọ́ lórí òdodo, ki eeyan ma si du àlámọ̀rí naa mọ́ wọn lọ́wọ́, ki èèyàn si maa tẹti ki èèyàn si maa tẹle àṣẹ wọn nibi itẹle ti Ọlọhun.
Ikarun-un: Ìmọ̀ràn fun awọn Mùsùlùmí: Pẹ̀lú ṣíṣe dáadáa si wọn ati pípè wọn, ati ki èèyàn má fi suta kan wọn, ati inifẹẹ oore fun wọn, ati kikun wọn lọ́wọ́ lori dáadáa ati ìpayà.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada Ti ede Azerbaijan Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Pipaṣẹ ìmọ̀ràn fun gbogbo èèyàn.
  2. Titobi ipò imọran ninu ẹsin.
  3. Ẹ̀sìn kó àwọn adisọkan ati awọn gbólóhùn ati awọn iṣẹ sínú.
  4. Lára imọran naa ni fifọ ẹmi mọ́ kuro nibi irẹjẹ fun ẹni ti a gba ni imọran ati gbigbero oore fun un.
  5. Ìkọ́ni-daadaa Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- níbi ti o ti dárúkọ nǹkan ni ṣókí, lẹ́yìn naa ni o wa sọ ọ ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.
  6. Bibẹrẹ pẹlu bi nǹkan ba ṣe pàtàkì jù tó, nibi ti Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ràn fun Ọlọhun, lẹyin naa fun tira Rẹ̀, lẹ́yìn náà fun ojiṣẹ Rẹ̀- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lẹ́yìn náà fun awọn aṣiwaju àwọn Mùsùlùmí, lẹyin naa fun gbogbo Musulumi ni apapọ.