عن أبي هريرة رضي الله عنه عن النبي صلى الله عليه وسلم قال:
«اجْتَنِبُوا السَّبْعَ الْمُوبِقَاتِ»، قَالُوا: يَا رَسُولَ اللهِ وَمَا هُنَّ؟ قَالَ: «الشِّرْكُ بِاللهِ، وَالسِّحْرُ، وَقَتْلُ النَّفْسِ الَّتِي حَرَّمَ اللهُ إِلَّا بِالْحَقِّ، وَأَكْلُ الرِّبَا، وَأَكْلُ مَالِ الْيَتِيمِ، وَالتَّوَلِّي يَوْمَ الزَّحْفِ، وَقَذْفُ الْمُحْصَنَاتِ الْمُؤْمِنَاتِ الْغَافِلَاتِ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 2766]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o gba a wa lati ọdọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, o sọ pe:
“Ẹ yẹra fún awọn nkan meje tí n pani run” Wọ́n sọ pé: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, kí ni awọn nkan naa? Ó ní: “Ṣíṣe ẹbọ pẹ̀lú Ọlọhun, pípidán, pípa eniyan tí Ọlọhun ṣe ní eewọ, àyàfi pẹlu ẹ̀tọ́, jíjẹ owó èlé, jíjẹ owó ọmọ òrukàn, sísálọ ní ọjọ́ ogun ẹsin, ati jíju òkò ṣina mọ́ awọn obinrin abilékọ, onígbàgbọ́ ododo, àwọn tí sìná kò sí lórí ọkàn wọn”.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 2766]
Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, n paṣẹ fún àwọn ijọ rẹ̀ pé kí wọ́n jinna sí awọn iwa ọdaran ati ẹṣẹ meje ti n pani run, nigba ti wọ́n wá bi i leere pé kí ni wọ́n? O ṣalaye pé àwọn ni:
Ikinni: Ṣíṣe ẹbọ pẹlu Ọlọhun, nipasẹ wíwá alafiwe ati alafijọ fun Un, èyí ó wù ki o jẹ, mimọ ni fún Ọlọhun, ati ṣiṣe eyikeyii ninu awọn ijọsin fún ẹlomiran tó yatọ si Ọlọhun Allah, Ọba Aleke ọla. Àti pé Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – bẹrẹ pẹlu ẹbọ; nitori pe oun ló tobi julọ ninu awọn ẹṣẹ.
Ikeji: Idán ṣíṣe – oun naa ni títa kókó àwọn nkankan, ati pípọfọ̀, ati awọn oogùn, ati awọn èéfín ti n rú jáde – yoo lapa lára ẹni tí wọ́n bá ṣe idan sí, bii kí o pa ẹni naa, tabi kí ó kó àisàn ba a, tabi kí ó fa ipinya laarin ọkọ ati aya. Iṣẹ ẹ̀ṣù ni, ati pé wọn ò lè rí ọpọlọpọ ninu awọn idan yi ṣe ayafi nipasẹ ẹbọ ati ìpèsè nkan ti awọn ẹ̀mí eṣu buruku nífẹ̀ẹ́ si fun wọn.
Ẹkẹta: Pípa ẹmi ti Ọlọhun ṣe ni eewọ lati pa a ayafi pẹ̀lú nǹkan ti o maa sọ ọ́ di ẹ̀tọ́ ti o ba ṣẹria mu ti oludajọ ṣẹria sì maa mu u ṣẹ.
Ẹkẹrin: Gbígba owo èlé lati lè jẹ́ ẹ tabi lilo o ní ọna miiran ninu awọn ọna anfaani.
Ìkarùn-ún: Ìtayọ àlà sí owó ọmọ kékeré tí bàbá rẹ̀ kú nígbà tí kò ì tíì bàlágà.
Ẹkẹfa: Sísá kúrò loju ogun ẹsin pẹ̀lú awọn keferi.
Ìkeje: Fífi ẹ̀sùn àgbèrè kan àwọn obìnrin olómìnira, oluṣọra nibi ìranù, àti fífi ẹ̀sùn kan àwọn ọkùnrin bakan naa.