عَن عُمَرَ بنِ الخَطَّابِ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُ قال: سَمِعْتُ النَّبِيَّ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يَقُولُ:
«لَا تُطْرُونِي كَمَا أَطْرَتِ النَّصَارَى ابْنَ مَرْيَمَ؛ فَإِنَّمَا أَنَا عَبْدُهُ، فَقُولُوا: عَبْدُ اللهِ وَرَسُولُهُ».
[صحيح] - [رواه البخاري] - [صحيح البخاري: 3445]
المزيــد ...
Lati ọdọ Umar ọmọ Al-Khattab - ki Ọlọhun yọnu si i - ó sọ pé: Mo gbọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tí ń ṣo pé:
"Ẹ má ṣe yìn mi jù gẹgẹ bi awọn Kristẹni ṣe yin ọmọ Maria jù; ẹrú Ọlọhun ni ẹmi n ṣe, nitori naa, ẹ wi pe: Ẹru Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ̀".
[O ni alaafia] - [Bukhaariy gba a wa] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 3445]
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n kọ̀ fun wa kuro nibi ìyinnijù ati ikọja aala ofin sharia nibi yiyin-in ati riroyin rẹ̀ pẹlu awọn iroyin Ọlọhun Ọba ati awọn iṣẹ tó jẹ́ ti Ọlọhun nikan ṣoṣo, tabi kí a sọ pé Anabi ní imọ kọ̀kọ̀, tabi ki a maa pe e papọ mọ Ọlọhun, gẹgẹ bi awọn Kristẹni ṣe ṣe pẹlu Isa ọmọ Maria - ki alaafia Ọlọhun maa ba a. Lẹyin naa, Anabi ṣalaye pé ẹru kan ninu awọn ẹru Ọlọhun ni oun, ó sì paṣẹ pé ki a maa sọ nipa oun bayii pé: Ẹru Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ̀.