+ -

عن عبد الله بن عمرو بن العاص رضي الله عنهما عن النبي صلى الله عليه وسلم قال:
«الْكَبَائِرُ: الْإِشْرَاكُ بِاللهِ، وَعُقُوقُ الْوَالِدَيْنِ، وَقَتْلُ النَّفْسِ، وَالْيَمِينُ الْغَمُوسُ».

[صحيح] - [رواه البخاري] - [صحيح البخاري: 6675]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amru ọmọ ‘Aas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:
“Awọn ẹṣẹ nlanla ni: Mimu orogun pẹlu Ọlọhun, ṣiṣẹ baba ati ìyá, pipa ẹmi, ati bibura lori irọ”.

[O ni alaafia] - [Bukhaariy gba a wa] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 6675]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe awọn nlanla ninu awọn ẹṣẹ, àwọn ni eyi ti wọn ṣe adehun iya fun ẹni ti o ba ṣe e pẹlu adehun iya ti o le koko ni aye tabi ni ọrun.
Akọkọ ninu ẹ ni “Mimu orogun pọ mọ Ọlọhun”: Oun ni yiyi eyikeyii iran ninu awọn iran ijọsin fun ẹni ti o yatọ si Ọlọhun, ati gbigbe ẹni ti o yatọ si Ọlọhun si ipo Ọlọhun nibi nnkan ti o jẹ awọn ẹsa Ọlọhun nibi ìní-ẹ̀tọ́ si ijọsin Rẹ, ati nibi jijẹ Oluwa Rẹ ati nibi awọn orukọ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ.
Ikeji nibẹ ni “Ṣiṣẹ baba ati iya”: Oun ni gbogbo nnkan ti o le sọ fifi suta kan baba ati iya di dandan ni ti ọrọ ni tabi iṣe, ati gbigbe ṣiṣe daadaa si wọn ju silẹ.
Ikẹta nibẹ ni “pipa ẹmi”: Laini ẹtọ, gẹgẹ bii pipa ẹmi ni ti abosi ati ni ti itayọ ẹnu-àlà.
Ikẹrin nibẹ ni “Bibura lori irọ”: Oun ni bibura ni ẹni tí n pa irọ ti o si mọ̀ pé irọ́ ni oun n pa, wọn sọ ọ ni orúkọ yẹn; nitori pe o maa n tẹ ẹni ti o n pa a ri sinu ẹṣẹ tabi inu ina.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف Ti ede Azerbaijan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Bibura lori irọ, ko si ìpẹ̀ṣẹ̀rẹ́ fun un; nitori lile koko ewu rẹ ati ẹṣẹ rẹ, bi ko ṣe pe ironupiwada ni o wa nibẹ.
  2. Wọn dárúkọ awọn ẹṣẹ nlanla mẹrin yii nìkan ninu hadiisi naa fun titobi ẹṣẹ wọn, kii ṣe pe àwọn nìkan naa ni ẹ̀ṣẹ̀ ńláǹlà.
  3. Awọn ẹṣẹ pin si nlanla ati keekeeke, awọn nlanla ni: Gbogbo ẹṣẹ ti ijiya ti aye n bẹ nibẹ, gẹgẹ bii ijiya ti sharia fi ààlà si, ati ègún, tabi adehun iya ti ọrun, gẹgẹ bii adehun iya pẹlu wiwọ ina, ati pe awọn ẹṣẹ nlanla ìpele ìpele ni wọn, awọn kan ninu wọn nipọn ju awọn kan lọ nibi jijẹ eewọ, awọn ẹṣẹ keekeeke ni awọn ti wọn yatọ si awọn ẹṣẹ ńláńlá.