+ -

عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه قال:
جَاءَ نَاسٌ مِنْ أَصْحَابِ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، فَسَأَلُوهُ: إِنَّا نَجِدُ فِي أَنْفُسِنَا مَا يَتَعَاظَمُ أَحَدُنَا أَنْ يَتَكَلَّمَ بِهِ، قَالَ: «وَقَدْ وَجَدْتُمُوهُ؟» قَالُوا: نَعَمْ، قَالَ: «ذَاكَ صَرِيحُ الْإِيمَانِ».

[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 132]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe:
Àwọn eniyan wa ninu awọn saabe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, wọn bi i leere pé: Dajudaju a n ri ninu ẹ̀mí wa nnkan ti ẹnikẹni nínú wa ko lee sọ ọ, o sọ pe: “Ṣé ẹ ti ri i?” Wọn sọ pé: Bẹẹni, o sọ pe: “Iyẹn ni igbagbọ ododo ti ko rùjú".

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 132]

Àlàyé

Àwọn ìjọ kan ninu awọn saabe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa, wọn si bi i leere nipa nnkan ti wọn n ri ninu ẹ̀mí wọn ninu awọn alamọri nla ti sisọ rẹ tobi latara biburu rẹ ati sisa wọn fun un, O sọ- Ki ikẹ Ọlọhun ati ọla maa ba a- pe: Dajudaju eyi ti ẹ ri ni igbagbọ òdodo ti ko ruju ati àmọ̀dájú ti o maa jẹ ki ẹ le kọ ohun ti èṣù n jù sinu ọkàn, ati kikọ wiwi i jade lẹ́nu, ati titobi ìyẹn ninu ẹ̀mí yin, ati pe èṣù ko ráyè ninu ọkàn yin, yatọ si ẹni ti èṣù ráyè ninu ọkan rẹ, ti ko si lee da a padà.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف البلغارية Ti ede Azerbaijan اليونانية Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية اللينجالا المقدونية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Alaye lilẹ èṣù pẹlu awọn oni igbagbọ nipa pe ko kapa nnkankan afi royiroyi.
  2. Aigbagbọ ati aigbawọle nnkan ti o n sọ sinu ẹ̀mí ninu awọn royiroyi; nitori pe o wa lati ọdọ èṣù.
  3. Royiroyi èṣù ko lee ni olugbagbọ lara, sugbọn ki o maa wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro nibi royiroyi rẹ, ki o si jawọ kuro nibi itẹsiwaju nibi ìyẹn.
  4. Didakẹ ko lẹtọọ fun Mùsùlùmí nipa nnkan ti o ba rú u lójú ninu alamọri ẹsin rẹ, o lẹtọọ fun un lati beere nipa rẹ.