عن أبي صِرْمة رضي الله عنه أن رسول الله صلى الله عليه وسلم قال:
«مَنْ ضَارَّ ضَارَّ اللهُ بِهِ، وَمَنْ شَاقَّ شَقَّ اللهُ عَلَيْهِ».
[حسن] - [رواه أبو داود والترمذي وابن ماجه وأحمد] - [سنن الترمذي: 1940]
المزيــد ...
Láti ọ̀dọ̀ Abu Sirmah- ki Ọlọhun yọnu si i- pe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Ẹni tí ó bá kó ìpalára ba ẹlòmíràn, Ọlọhun maa ko ìpalára ba oun naa, ẹni tí ó bá ko ìnira ba ẹlòmíràn, Ọlọhun maa ko ìnira ba oun naa”.
[O daa] - [Abu Daud ati Tirmiziy ati Ibnu Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a wa] - [Sunanu ti Tirmidhiy - 1940]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣọ wa lara kuro nibi mimu ìpalára wọlé tọ Musulumi, tabi fifi ìnira kan an nibi èyíkéyìí àlámọ̀rí; yálà nibi ẹ̀mí rẹ ni, tabi dúkìá rẹ, tabi ará-ilé rẹ. Ẹni tí ó bá wa ṣe iyẹn, Ọlọhun maa san an ni ẹsan, O si maa fi ìyà jẹ ẹ ninu iran iṣẹ ti o ṣe.