+ -

عَنْ أَبِي سَعِيدٍ الخُدْرِيِّ رضي الله عنه أَنَّ رَسُولَ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«إِذَا سَمِعْتُمُ النِّدَاءَ، فَقُولُوا مِثْلَ مَا يَقُولُ المُؤَذِّنُ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 611]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Sa‘ēd Al-khudriyy - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:
«Tí ẹ ba ti gbọ ipe irun, ki ẹ yaa maa sọ iru nkan ti oluperun ba n sọ».

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 611]

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣeni lojukokoro lori jijẹ ipe oluperun nigba ti a ba n gbọ ọ, ati pe ìyẹn ni ki a maa sọ nkan ti o n sọ, ni gbolohun gbolohun. Nigba ti o ba wa sọ gbolohun Allāh Akbar àwa naa o wi i lẹyin rẹ, ati pe nigba ti o ba mu gbolohun ijẹrii mejeeji wa, awa naa o mu un wa lẹ́yìn rẹ, Ati pe wọn ṣe ayaafi gbolohun: (Hayya ‘alas sọlāt, Hayya ‘alal falāh) wọn maa sọ lẹyin awọn mejeeji pe: lā haola walā quwwata illā biLlāh.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Ede Jamani Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف Ti ede Azerbaijan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Yio maa tẹle oluperun keji lẹyin ti alakọkọọ ba pari, koda ki awọn oluperun o pọ! Latari kikari hadīth yii.
  2. Yio maa jẹ ipe oluperun (yio maa sọ nkan ti o ba n sọ) ni gbogbo iṣesi rẹ, ti ko ba ti si ni ile ẹgbin tabi lori bukaata rẹ (itọ tabi igbẹ).