+ -

عَنْ أَبِي سَعِيدٍ الْخُدْرِيِّ رضي الله عنه عَنِ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«إِنَّ الدُّنْيَا حُلْوَةٌ خَضِرَةٌ، وَإِنَّ اللهَ مُسْتَخْلِفُكُمْ فِيهَا، فَيَنْظُرُ كَيْفَ تَعْمَلُونَ، فَاتَّقُوا الدُّنْيَا وَاتَّقُوا النِّسَاءَ، فَإِنَّ أَوَّلَ فِتْنَةِ بَنِي إِسْرَائِيلَ كَانَتْ فِي النِّسَاءِ».

[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 2742]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Sa'eed Al-Khudriy- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:
"Dajudaju aye jẹ nnkan ti o dun ti o si tutu, ati pe dajudaju Ọlọhun n fi yin ṣe arole nibẹ, ti yoo maa wo nnkan ti ẹ ń ṣe, ẹ bẹru aye ki ẹ si bẹru obinrin, dajudaju akọkọ fitina awọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ lara obinrin".

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 2742]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe dajudaju aye dun nibi itọwo, o si tutu nibi riri, ti ọmọniyan maa gba ẹtanjẹ pẹlu rẹ ti yoo si tẹ̀rì sinu rẹ ti yoo si sọ ọ di eyi ti o tobi julọ ninu ironu rẹ. Ati pe dajudaju Ọlọhun- mimọ ni fun Un- fi awọn kan ninu wa role fun awọn kan ni igbesi aye yìí, ki O le maa wo bi a ṣe maa ṣiṣẹ, njẹ a maa tẹle E, tabi a maa yapa Rẹ? Lẹyin naa, o sọ pe: Ẹ ṣọ́ra ki igbadun aye ati ọṣọ rẹ ma tan yin jẹ, ti o wa maa mu yin gbe nnkan ti Ọlọhun pa yin láṣẹ rẹ ju silẹ, ati kiko si nnkan ti O kọ kuro fun yin nibẹ. Ati pe ninu nnkan ti o jẹ dandan julọ lati ṣọ́ra kuro ninu rẹ ninu awọn wahala aye ni wahala obinrin, ati pe o jẹ akọkọ wahala ti awọn ọmọ Ísírẹ́lì ko síbẹ̀.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Ede Jamani Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف Ti ede Azerbaijan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣisẹnilojukokoro lori idunnimọ ibẹru, ati aiko akolekan pẹlu awọn nnkan adun aye ati ọṣọ rẹ.
  2. Ikilọ kuro nibi fitina obinrin, ninu wiwo tabi fifi ọwọ́ dẹngẹrẹ mú iropọ wọn pẹlu awọn ọkunrin ajoji, tabi eyi ti o yàtọ̀ si ìyẹn.
  3. Fitina obinrin wa ninu eyi ti o tobi julọ ninu awọn fitina ni aye.
  4. Gbigba waasu ati gbigba ariwoye mu lara awọn ijọ ìṣáájú, ati pe nnkan ti o ṣẹlẹ̀ si awọn ọmọ Ísírẹ́lì le ṣẹlẹ̀ si awọn ti wọn yàtọ̀ si wọn.
  5. Fitina obinrin ti o ba jẹ iyawo, o le la bọ ọkùnrin lọrun ninu inawo ni nnkan ti ko lagbara rẹ, ti yoo wa ko airoju ba a lati wa awọn àlámọ̀rí ẹsin, ti yoo ti i lọ sibi fifi ẹmi ara rẹ̀ wéwu lori wiwa ayé, ti obinrin naa ba jẹ ajoji, fitina rẹ ni fifa oju awọn ọkunrin mọra ati iko iyẹgẹrẹ ba wọn kuro nibi ododo ti wọn ba ti jade ti wọn ba si ti ropọ mọ wọn, pàtàkì julọ ti wọn ba jẹ obinrin ti wọn kò bo ojú ti wọn si ṣira silẹ, eleyii le ja si ṣìná pẹlu awọn ipele rẹ, o wa tọ fun olugbagbọ lati dirọ mọ Ọlọhun, ati ifi erongba han si I nibi igbala kuro nibi wahala wọn.