+ -

عَنْ أَنَسٍ رضي الله عنه قَالَ:
جَاءَ رَجُلٌ إِلَى النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ فَقَالَ: يَا رَسُولَ اللهِ، مَا تَرَكْتُ حَاجَّةً وَلَا دَاجَّةً إِلَّا قَدْ أَتَيْتُ، قَالَ: «أَلَيْسَ تَشْهَدُ أَنْ لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ وَأَنَّ مُحَمَّدًا رَسُولُ اللهِ؟» ثَلَاثَ مَرَّاتٍ. قَالَ: نَعَمْ، قَالَ: «فَإِنَّ ذَلِكَ يَأْتِي عَلَى ذَلِكَ».

[صحيح] - [رواه أبو يعلى والطبراني والضياء المقدسي] - [الأحاديث المختارة للضياء المقدسي: 1773]
المزيــد ...

Lati ọdọ Anas- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe:
Arakunrin kan wa sọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, mi ko fi ẹṣẹ kankan sílẹ̀ láì dá, o sọ pe: “Njẹ ṣe ko ki n ṣe pe o n jẹrii pe ko si ẹni ti ìjọsìn tọ si òdodo afi Allahu ni, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni? Ni ẹẹmẹta. O sọ pe: bẹẹni, Anabi sọ pe Dajudaju ìyẹn maa pa àwọn ẹṣẹ yẹn rẹ.

[O ni alaafia] - [Abu Yahlaa ati Tọbarọọniy ati Ad-Diyaau Al-Makdisiy ni wọn gba a wa] - [Àwọn hadiisi ti a ṣẹsa fun Ad-Diyaahul Makdisiy - 1773]

Àlàyé

Arakunrin kan wa sọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, dajudaju mo ti da gbogbo ẹṣẹ, ti mi ko fi ẹṣẹ kekere tabi ńlá kalẹ afi ki n ti ṣe e, njẹ wọn maa forí jin mi? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun un pé: Njẹ ṣe ko ki n ṣe pe o n jẹrii pe ko si ẹni ti ìjọsìn tọ si ni ododo afi Allahu ni, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni? O paara rẹ ni ẹẹmẹta, O da a lohun pe: Bẹẹni mo n jẹrii, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ ọla ti o n bẹ fun ijẹrii mejeeji fun un ati pipa awọn aburu rẹ̀ rẹ́, ati pe ironupiwada maa n pa nnkan ti o ṣíwájú rẹ rẹ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada Ti ede Azerbaijan Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Titobi ijẹrii mejeeji ati titẹṣuwọn rẹ lori awọn ẹṣẹ fun ẹni ti o ba sọ ọ lododo lati inu ọkan rẹ.
  2. Isilaamu maa n pa nnkan ti o ṣíwájú rẹ rẹ.
  3. Ironupiwada ododo maa n pa nnkan ti o ṣíwájú rẹ rẹ.
  4. Pipaara nnkan ninu idanilẹkọọ wa ninu imọna Anabi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a).
  5. Ọla ti o n bẹ fun ijẹrii mejeeji, ati pe mejeeji jẹ okunfa fun igbala kuro nibi ṣíṣe gbere ninu ina.