عن أبي الدرداء رضي الله عنه عن النبي صلى الله عليه وسلم قال:
«مَنْ رَدَّ عَنْ عِرْضِ أَخِيهِ رَدَّ اللهُ عَنْ وَجْهِهِ النَّارَ يَوْمَ الْقِيَامَةِ».
[صحيح] - [رواه الترمذي وأحمد] - [سنن الترمذي: 1931]
المزيــد ...
Láti ọ̀dọ̀ Abu Ad-Dardaa- ki Ọlọhun yọnu si i- láti ọ̀dọ̀ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pé:
“Ẹni ti o ba dáàbò bo iyì ọmọ-ìyá rẹ, Ọlọhun maa dáàbò bo ojú rẹ kuro nibi iná ni Ọjọ́ Àjíǹde”.
[O ni alaafia] - [Tirmiziy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa] - [Sunanu ti Tirmidhiy - 1931]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé ẹni tí ó bá dáàbò bo iyì ọmọ-iya rẹ ti o jẹ Mùsùlùmí lẹ́yìn ti ko jẹ ki wọn bu u tabi ṣe aburú si i, Ọlọhun maa dáàbò bo oun naa kuro nibi ìyà ni Ọjọ́ Àjíǹde.