عن عبد الله بن عمر رضي الله عنهما قال:
سَمِعَ النَّبِيُّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ رَجُلًا يَعِظُ أَخَاهُ فِي الْحَيَاءِ، فَقَالَ: «الْحَيَاءُ مِنَ الْإِيمَانِ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح مسلم: 36]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Umar- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- o sọ pé:
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- gbọ ti arákùnrin kan n ṣe wáàsí fun ọmọ-iya rẹ nipa ìtìjú, o wa sọ pé: “Itiju wa ninu igbagbọ”.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Muslim - 36]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- gbọ ti arákùnrin kan n gba ọmọ-ìyá rẹ ni imọran pe ki o fi àpọ̀jù itiju silẹ! O wa ṣàlàyé fun un pe ìtìjú wa ninu ìgbàgbọ́, ko si lee mu nǹkan kan wa ayafi oore.
Ìtìjú jẹ iwa kan ti o maa n mu èèyàn ṣe dáadáa, ti o si maa n mu èèyàn fi ohun buruku silẹ.