+ -

عَنْ أَبِي عَبْدِ الرَّحْمَنِ السُّلَمي رحمه الله قَالَ:
حَدَّثَنَا مَنْ كَانَ يُقْرِئُنَا مِنْ أَصْحَابِ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ أَنَّهُمْ كَانُوا يَقْتَرِئُونَ مِنْ رَسُولِ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ عَشْرَ آيَاتٍ، فَلَا يَأْخُذُونَ فِي الْعَشْرِ الْأُخْرَى حَتَّى يَعْلَمُوا مَا فِي هَذِهِ مِنَ الْعِلْمِ وَالْعَمَلِ، قَالُوا: فَعَلِمْنَا الْعِلْمَ وَالْعَمَلَ.

[حسن] - [رواه أحمد] - [مسند أحمد: 23482]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Abdir-Rahmaan As-Sulamiy- ki Ọlọhun kẹ́ ẹ- o sọ pe:
Awọn ti wọn maa n kọ́ wa bi a ṣe maa ka Kuraani ninu awọn saabe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun wa pe àwọn maa n gba aaya mẹ́wàá lọ́dọ̀ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- àwọn ko nii gba mẹ́wàá miiran titi ti àwọn fi maa mọ imọ ati iṣẹ ti o wa ninu ẹ, wọn sọ pé: A wa kọ́ imọ ati iṣẹ.

[O daa] - [Ahmad ni o gba a wa] - [Musnad ti Ahmad - 23482]

Àlàyé

Awọn saabe- ki Ọlọhun yọnu si wọn- maa n gba aaya mẹ́wàá lọ́dọ̀ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ninu Kuraani, wọn ko si nii bọ si ibòmíràn titi ti wọn fi maa kọ́ imọ ti o wa ninu awọn aaya mẹ́wàá yii ti wọn si maa lò ó, o maa waa ja si pe wọn kọ imọ ati iṣẹ papọ nìyẹn.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada Ti ede Azerbaijan Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ọla ti n bẹ fun awọn saabe- ki Ọlọhun yọnu si wọn- ati ojúkòkòrò wọn lori kíkọ́ Kuraani.
  2. Kíkọ́ Kuraani maa wáyé pẹ̀lú imọ ati lilo o, kii ṣe pẹ̀lú kika a ati hiha a nìkan.
  3. Ìmọ̀ maa wáyé ṣiwaju ọ̀rọ̀ ati iṣẹ.
Àlékún