+ -

عَنْ عَبْدِ اللَّهِ بْنِ عَمْرٍو رضي الله عنهما قَالَ: قالَ النَّبِيُّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«حَوْضِي مَسِيرَةُ شَهْرٍ، مَاؤُهُ أَبْيَضُ مِنَ اللَّبَنِ، وَرِيحُهُ أَطْيَبُ مِنَ المِسْكِ، وَكِيزَانُهُ كَنُجُومِ السَّمَاءِ، مَنْ شَرِبَ مِنْهَا فَلاَ يَظْمَأُ أَبَدًا».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 6579]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abdullah ọmọ Amr, ki Olohun yọnu si awọn mejeeji, o sọ pe: Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, sọ pe:
Abàtà mi, ìrìn oṣù kan ni, omi rẹ̀ funfun ju wàrà lọ, òórùn rẹ̀ dùn ju alumisiki lọ , ife rẹ̀ sì dà bii ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ẹni tí ó bá mu nínú ẹ, òùngbẹ kò nii gbẹ ẹ́ láéláé.”

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 6579]

Àlàyé

Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a, sọ pe oun yoo ni abàtà kan ni Ọjọ Ajinde, ti òró rẹ yoo jẹ irin oṣu kan, ti ìbú rẹ naa si maa jẹ irin oṣù kan, Omi rẹ funfun ju wara lọ, Oorun rẹ dun ju ti alumisiki lọ, Àwọn àgé omi rẹ̀ pọ̀ bíi ìràwọ̀ ojú ọ̀run, Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi àgé omi náà mu omi ninu abata naa, òùngbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láéláé.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè Fulani Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف البلغارية Ti ede Azerbaijan اليونانية Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية اللينجالا المقدونية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Abata ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- jẹ ibi ti omi kó jọ si ti o tóbi ti àwọn onigbagbọ ninu ijọ rẹ maa wa síbẹ̀ ni ọjọ́ alukiyaamọ.
  2. Ṣiṣẹlẹ igbadun fun ẹni ti o ba mu ninu abata naa, òùngbẹ ko nii gbẹ ẹ mọ láéláé.