+ -

عَنْ عَائِشَةَ رضي الله عنها قَالَتْ:
قُلْتُ: يَا رَسُولَ اللهِ، ابْنُ جُدْعَانَ كَانَ فِي الْجَاهِلِيَّةِ يَصِلُ الرَّحِمَ، وَيُطْعِمُ الْمِسْكِينَ، فَهَلْ ذَاكَ نَافِعُهُ؟ قَالَ: «لَا يَنْفَعُهُ، إِنَّهُ لَمْ يَقُلْ يَوْمًا: رَبِّ اغْفِرْ لِي خَطِيئَتِي يَوْمَ الدِّينِ».

[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 214]
المزيــد ...

Lati ọdọ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe:
Mo sọ pé: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, Ibnu Jud’aan maa n da ibi pọ ni asiko ki Isilaamu to de, o si maa n fun awọn alaini ni oúnjẹ, njẹ ìyẹn maa ṣe e ni anfaani? O sọ pe: “Ko lee ṣe e ni anfaani, nitori pe ko fi ọjọ kan sọ pé: Irẹ Oluwa mi, fori awọn àṣìṣe mi jin mi ni ọjọ ẹsan".

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 214]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ nipa Abdullahi Bn Jud’aan, o si wa ninu awọn aṣiwaju Kuraiṣi ṣíwájú Isilaamu, Ninu awọn iṣẹ daadaa rẹ ni pé: O maa n da awọn ẹbi pọ, o si maa n ṣe daadaa si wọn, o si maa n fun alaini ni oúnjẹ, ati eyi ti o yàtọ̀ si wọn ninu awọn iwa ọlọla ti Isilaamu ṣe wa lojukokoro lori ṣíṣe wọn, ati pe awọn iṣẹ yii ko lee ṣe e ni anfaani ni ọjọ igbedide rẹ; ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ fun okunfa ṣíṣe aigbagbọ rẹ ninu Ọlọhun, ati pe ko fi ọjọ kan sọ pé: Irẹ Oluwa mi, forí awọn àṣìṣe mi jin mi ni ọjọ ẹsan.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف البلغارية Ti ede Azerbaijan اليونانية Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية اللينجالا المقدونية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Alaye ọla ti o n bẹ fun nini igbagbọ, ati pe o jẹ majẹmu fun gbigba awọn iṣẹ.
  2. Alaye apẹrẹ buruku aigbagbọ, ati pe o wa ninu awọn nnkan ti o n ba awọn iṣẹ oloore jẹ.
  3. Àwọn alaigbagbọ, awọn iṣẹ wọn ko nii ṣe wọn ni anfaani ni ọjọ igbedide nitori aigbagbọ wọn ninu Ọlọhun ati ọjọ igbedide.
  4. Àwọn iṣẹ́ ọmọniyan ni ipo aigbagbọ rẹ, wọn maa kọ wọn fun un ti o ba gba Isilaamu, wọn yoo si san an ni ẹsan lori wọn.