عن أنس رضي الله عنه قال: قال النبي صلى الله عليه وسلم:
«لَا يُؤْمِنُ أَحَدُكُمْ حَتَّى أَكُونَ أَحَبَّ إِلَيْهِ مِنْ وَالِدِهِ وَوَلَدِهِ وَالنَّاسِ أَجْمَعِينَ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 15]
المزيــد ...

Lati ọdọ Anas- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Ẹni kan kan ninu yin ko nii gbagbọ ni ododo titi ti yoo fi nífẹ̀ẹ́ mi ju baba rẹ, ati ọmọ rẹ, ati awọn èèyàn ni apapọ lọ”.

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 15]

Àlàyé

Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ fun wa pe Musulumi ko nii jẹ ẹni tí igbagbọ rẹ pe titi ti yoo fi ti ìfẹ́ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣáájú ìfẹ́ ìyá rẹ, ati baba rẹ, ati ọmọkùnrin rẹ, ati ọmọbìnrin rẹ, ati awọn èèyàn ni apapọ, ìfẹ́ yii n beere fun itẹle e ati riran an lọ́wọ́, ati ki èèyàn ma yapa rẹ.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Dandan ni níní ìfẹ́ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ati titi i ṣáájú ìfẹ́ gbogbo ẹ̀dá.
  2. Lara ami pípé ìfẹ́ ni: Ríran sunna ojiṣẹ Ọlọhun lọ́wọ́, ati níná ẹ̀mí ati dúkìá tori rẹ.
  3. Ifẹ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n beere fun itẹle e nibi àṣẹ ti o ba pa, ati gbigba a ni olódodo nibi ohun ti o ba sọ, ati jíjìnnà si ohun ti o ba kọ̀, ati itẹle e, ati fifi adadaalẹ sílẹ̀.
  4. Ẹ̀tọ́ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- tobi o si kanpá ju ti gbogbo èèyàn lọ; torí pé o jẹ okùnfà imọna wa kúrò nibi anù, ati yíyọ wa kuro nibi iná, ati wiwọ alujanna.
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Èdè: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Àlékún (62)