+ -

عن عمر بن الخطاب رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«إِنَّمَا الْأَعْمَالُ بِالنِّيَّةِ، وَإِنَّمَا لِامْرِئٍ مَا نَوَى، فَمَنْ كَانَتْ هِجْرَتُهُ إِلَى اللهِ وَرَسُولِهِ، فَهِجْرَتُهُ إِلَى اللهِ وَرَسُولِهِ، وَمَنْ كَانَتْ هِجْرَتُهُ لِدُنْيَا يُصِيبُهَا أَوِ امْرَأَةٍ يَتَزَوَّجُهَا، فَهِجْرَتُهُ إِلَى مَا هَاجَرَ إِلَيْهِ». وفي لفظ للبخاري: «إِنَّمَا الْأَعْمَالُ بِالنِّيَّاتِ، وَإِنَّمَا لِكُلِّ امْرِئٍ مَا نَوَى».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح مسلم: 1907]
المزيــد ...

Lati ọdọ Umar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Àwọn iṣẹ́ pẹlu àníyàn ni, ohun ti ọmọniyan ba gba lero ni yoo maa jẹ tiẹ̀, ẹni tí hijra tiẹ̀ ba jẹ tori ti Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ, hijra rẹ maa jẹ ti Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ, ẹni tí hijra rẹ ba jẹ torí ayé ti o fẹ ki ọwọ rẹ o tẹ̀ tabi torí obìnrin ti o fẹ́ fẹ́, hijra rẹ maa jẹ ohun ti o ba tori rẹ ṣe hijra ni”. Ninu gbólóhùn kan ti o jẹ ti Bukhaariy: “Àwọn iṣẹ pẹ̀lú àwọn àníyàn ni, o maa jẹ ti ọmọniyan kọ̀ọ̀kan ohun ti o ba gba lero”.

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Muslim - 1907]

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe gbogbo iṣẹ́ pẹlu àníyàn ni, ìdájọ́ yii kárí gbogbo iṣẹ́ bii ìjọsìn ati ibalopọ. Ẹni ti o ba gbèrò anfaani kan pẹlu iṣẹ rẹ, anfaani yẹn naa ni o maa tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́, ko si si ẹsan kankan fun un, ẹni tí ó bá wa gbèrò isunmọ Ọlọhun pẹlu iṣẹ rẹ, o maa gba ẹsan kódà ki o jẹ iṣẹ lásán bii jijẹ ati mimu.
Lẹ́yìn naa ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa fi àkàwé lélẹ̀ láti ṣàlàyé ilapa àníyàn nibi awọn iṣẹ pẹ̀lú didọgba wọn nibi àwòrán ti o hàn, o wa ṣàlàyé pe ẹni ti o ba gbèrò wíwá ìyọ́nú Ọlọhun pẹ̀lú hijra rẹ ati fifi ìlú rẹ sílẹ̀, hijra rẹ nǹkan ti o ba òfin mu ni ti a si maa tẹ́wọ́ gbà ti wọn si maa san an ni ẹsan lórí ẹ fun àníyàn òdodo rẹ, ẹni tí ó bá gbèrò anfaani ayé pẹ̀lú hijra rẹ, bii owó, tabi ipò, tabi òwò, tabi ìyàwó, anfaani yẹn ti o gbèrò naa ni o maa ri nibi hijra rẹ, ko si nii gba ẹsan.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè Fulani Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف البلغارية Ti ede Azerbaijan Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية اللينجالا المقدونية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Isẹnilojukokoro lori imọkanga; tori pe Ọlọhun ko nii gba iṣẹ ayafi eyi ti wọn ba fi wa oju-rere Rẹ̀.
  2. Awọn iṣẹ ti a fi maa n sunmọ Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn, ti ẹni tí o ti bàlágà ba ṣe e ni ti àṣà, ko nii gba ẹsan titi ti yoo fi gbero isunmọ Ọlọhun pẹlu ẹ.