+ -

عَنْ عُثْمَانَ رضي الله عنه قَالَ: سَمِعْتُ رَسُولَ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يَقُولُ:
«مَا مِنَ امْرِئٍ مُسْلِمٍ تَحْضُرُهُ صَلَاةٌ مَكْتُوبَةٌ فَيُحْسِنُ وُضُوءَهَا وَخُشُوعَهَا وَرُكُوعَهَا، إِلَّا كَانَتْ كَفَّارَةً لِمَا قَبْلَهَا مِنَ الذُّنُوبِ، مَا لَمْ يُؤْتِ كَبِيرَةً، وَذَلِكَ الدَّهْرَ كُلَّهُ».

[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 228]
المزيــد ...

Lati ọdọ 'Uthman- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe:
"Ko si ninu ọmọniyan to jẹ musulumi ti irun ọran-anyan kan wa ba a, ti o wa ṣe aluwala rẹ daadaa ati ipaya rẹ ati rukuu rẹ, afi ki o jẹ ipa ẹṣẹ rẹ fun nnkan ti o ṣíwájú ninu awọn ẹṣẹ, niwọn igba ti ko ba mu ẹṣẹ nla wa, gbogbo igba si ni ìyẹn maa ri bẹ́ẹ̀".

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 228]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju ko si ninu musulumi kan ti asiko irun ọran-anyan maa wọle ba a ti o si ṣe aluwala rẹ daadaa ti o si pe e, lẹyin naa o n paya nibi irun rẹ pẹlu pe ọkan rẹ ati awọn orikee rẹ gbogbo rẹ dojukọ Ọlọhun ti wọn n ranti titobi Rẹ lori irun, O si pe awọn iṣẹ irun gẹgẹ bii rukuu ati iforikanlẹ ati eyi ti o yàtọ̀ si i, afi ki irun yii jẹ ipa ẹṣẹ rẹ fun nnkan ti o ṣíwájú ninu awọn ẹṣẹ kekere, niwọn igba ti ko ba ti da ẹṣẹ nla kan ninu awọn ti o tobi ninu awọn ẹṣẹ, ati pe ọla yii ma maa lọ bẹẹ pẹlu lilọ igba ati nibi gbogbo irun.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Irun jẹ ipa ẹṣẹ rẹ fun awọn ẹṣẹ, oun ni eyi ti ẹru ba ṣe aluwala rẹ daadaa, ti o si ki i ni olupaya ti o fi wa oju rere Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-.
  2. Ọla ti o n bẹ fun idunnimọ awọn ijọsin, ati pe o jẹ okunfa fun aforijin awọn ti wọn kere ninu awọn ẹṣẹ.
  3. Ọla ti o n bẹ fun ṣíṣe aluwala daadaa, ati kiki irun daadaa ati nini ipaya nibẹ.
  4. Pataki jijina si awọn ti o tobi ninu awọn ẹṣẹ lati ṣe aforijin àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kéékèèké.
  5. Awọn ẹṣẹ ńláńlá ko ṣee parẹ afi pẹlu ironupiwada.