+ -

عَنْ مُعَاذٍ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُ، قَالَ:
كُنْتُ رِدْفَ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ عَلَى حِمَارٍ يُقَالُ لَهُ عُفَيْرٌ، فَقَالَ: «يَا مُعَاذُ، هَلْ تَدْرِي حَقَّ اللَّهِ عَلَى عِبَادِهِ، وَمَا حَقُّ العِبَادِ عَلَى اللَّهِ؟»، قُلْتُ: اللَّهُ وَرَسُولُهُ أَعْلَمُ، قَالَ: «فَإِنَّ حَقَّ اللَّهِ عَلَى العِبَادِ أَنْ يَعْبُدُوهُ وَلا يُشْرِكُوا بِهِ شَيْئًا، وَحَقَّ العِبَادِ عَلَى اللَّهِ أَنْ لا يُعَذِّبَ مَنْ لا يُشْرِكُ بِهِ شَيْئًا»، فَقُلْتُ: يَا رَسُولَ اللَّهِ أَفَلاَ أُبَشِّرُ بِهِ النَّاسَ؟ قَالَ: «لا تُبَشِّرْهُمْ، فَيَتَّكِلُوا».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 2856]
المزيــد ...

Lati ọdọ Mu’aadh- ki Ọlọhun yọnu si i-, o sọ pe:
Mo wa lẹyin Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori kẹtẹkẹtẹ kan ti wọn n pe ni ‘Ufair, o sọ pe: “Irẹ Mu’aadh, njẹ o mọ iwọ Ọlọhun lori awọn ẹrusin Rẹ, ati nnkan ti o jẹ iwọ àwọn ẹrusin lori Ọlọhun?”, mo sọ pe: Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ ni wọn ni imọ julọ, o sọ pe: “Dajudaju iwọ Ọlọhun lori awọn ẹrusin ni ki wọn maa jọsin fun Un ki wọn si ma da nnkan pọ mọ Ọn ninu ẹbọ, iwọ àwọn ẹrusin lori Ọlọhun ni ki O ma fi iya jẹ ẹni ti ko ba da nnkan pọ mọ Ọn ninu ẹbọ”, mo sọ pe: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, ṣe ki n maa fun awọn eniyan ni iro idunnu nipa rẹ? O sọ pe: “Rara, ma fun wọn ni iro ìdùnnú, ki wọn ma baa gbára lé e”.

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 2856]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé iwọ Ọlọhun lori awọn ẹrusin, ati iwọ awọn ẹrusin lori Ọlọhun, ati pe iwọ Ọlọhun lori awọn ẹrusin ni ki wọn maa jọsin fun Un ni Oun nikan ṣoṣo ki wọn si ma da nnkan kan pọ mọ Ọn ninu ẹbọ, Ati pe iwọ awọn ẹrusin lori Ọlọhun ni ki O ma fi iya jẹ awọn ti wọn mu U ni Ọkan ti wọn ko da nnkan pọ mọ Ọn ninu ẹbọ. Lẹyin naa Mu’aadh sọ pé: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, njẹ mi ko nii fun awọn eniyan ni iro ki wọn le dunnu pẹlu ọla yìí? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ fun un ni ti ipaya ki wọn maa gbe ara le e.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف البلغارية Ti ede Azerbaijan اليونانية Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية اللينجالا المقدونية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Alaye iwọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ti O ṣe e ni dandan lori awọn ẹrusin Rẹ, oun ni ki wọn maa jọsin fun Un, ki wọn si ma da nnkan pọ mọ Ọn ninu ẹbọ.
  2. Alaye iwọ awọn ẹrusin lori Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ti O ṣe e ni dandan fun ara Rẹ ni ti ọla lati ọdọ Rẹ ati idẹra, oun ni ki O mu wọn wọ alujanna, ki o si ma fi iya jẹ wọn.
  3. Iro idunnu ti o tobi n bẹ nibẹ fun awọn ti wọn mu U ni Ọkan ti wọn ko da nnkan pọ mọ Ọn ninu ẹbọ pe ìkángun wọn ni wiwọ alujanna.
  4. Mu’aadh sọ hadisi yii ṣíwájú iku rẹ; ni ti ipaya kiko si inu ẹṣẹ fifi imọ pamọ.
  5. Akiyesi lori aima fọn apakan awọn hadisi ka lọdọ awọn eniyan kan ni ti ibẹru lori ẹni ti ko ni imọ nipa ìtumọ̀ rẹ; ìyẹn nibi nnkan ti ko si iṣẹ lábẹ́ rẹ tabi ìjìyà kan ninu awọn ìjìyà Sharia.
  6. Àwọn ẹlẹṣẹ nínú awọn ti wọn mu Ọlọhun ni Ọkan ṣoṣo wa lábẹ́ fifẹ Ọlọhun, ti O ba fẹ yoo fi iya jẹ wọn ti O ba si fẹ yoo fori jin wọn, lẹyin naa ìkángun wọn maa jẹ alujanna.