+ -

عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه أَنَّ رَسُولَ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«إِذَا تَوَضَّأَ أَحَدُكُمْ فَلْيَجْعَلْ فِي أَنْفِهِ ثُمَّ لِيَنْثُرْ، وَمَنِ اسْتَجْمَرَ فَلْيُوتِرْ، وَإِذَا اسْتَيْقَظَ أَحَدُكُمْ مِنْ نَوْمِهِ فَلْيَغْسِلْ يَدَهُ قَبْلَ أَنْ يُدْخِلَهَا فِي وَضُوئِهِ، فَإِنَّ أَحَدَكُمْ لاَ يَدْرِي أَيْنَ بَاتَتْ يَدُهُ». ولفظ مسلم: «إِذَا اسْتَيْقَظَ أَحَدُكُمْ مِنْ نَوْمِهِ فَلَا يَغْمِسْ يَدَهُ فِي الْإِنَاءِ حَتَّى يَغْسِلَهَا ثَلَاثًا، فَإِنَّهُ لَا يَدْرِي أَيْنَ بَاتَتْ يَدُهُ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 162]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe:
"Ti ẹnikẹni ninu yin ba ṣe aluwala ki o ya fi omi si imu rẹ lẹyin naa ki o fin in síta, ẹni ti o ba fẹ fi okuta mọra ki o ya ṣe e ni witiri, ti ẹnikẹni ninu yin ba ji lati oju orun rẹ ki o yaa fọ ọwọ rẹ ṣíwájú ki o to ti mejeeji bọ inu omi aluwala rẹ, nitori pe ẹnikẹni ninu yin ko mọ ibi ti ọwọ rẹ wa mọju". Ati ẹgbawa Muslim: "Ti ẹnikẹni ninu yin ba ti ji lati oju orun rẹ, ki o ma ti ọwọ rẹ bọ inu igba titi yoo fi fọ ọ lẹẹmeta, nitori pe ko mọ ibi ti ọwọ rẹ wa mọju".

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 162]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé awọn kan ninu awọn idajọ imọra, ninu wọn ni: Akọkọ: Dajudaju ẹni ti o ba ṣe aluwala, o jẹ dandan fun un lati fi omi si imu rẹ pẹlu èémí, lẹyin naa yoo mu u jade pẹlu eemi bakannaa. Ikeji: Ẹni ti o ba fẹ mọ ẹgbin ti o n jade lati ara rẹ, ti o fẹ mu u kuro pẹlu nnkan ti o yàtọ̀ si omi gẹgẹ bii okuta ati nnkan ti o jọ ọ, ki mimọra rẹ jẹ lori onka ti meji o le pin ti eyi ti o kere julọ nibẹ jẹ mẹta, ti eyi ti o pọ julọ nibẹ jẹ nnkan ti nnkan ti o n jade fi maa dá pẹlu rẹ ti aaye naa si fi maa mọ. Ikẹta ni: Ẹni ti o ba ji lati oju orun oru ko nii ti atẹlẹwọ rẹ bọ inu igba lati ṣe aluwala titi yoo fi fọ ọ lẹẹmẹta sita igba, nitori pe ko mọ ibi ti ọwọ rẹ wa mọju, ko lee fọkanbalẹ nipa ẹgbin lori rẹ, Shaitan ti le ba a ṣere ti o le ti gbe awọn nnkan ti o le ko inira ba eniyan sibẹ tabi nnkan ti o le ba omi jẹ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Ede Jamani Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف Ti ede Azerbaijan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Fifin omi si imu jẹ dandan nibi aluwala, oun ni: Mimu omi wọle sinu imu pẹlu ọna eemi, gẹgẹ bẹẹ naa ni fifin omi síta, oun ni: Mimu omi jade lati inu imu pẹlu ọna eemi.
  2. Ṣíṣe mimọra pẹlu okuta ni nnkan ti a fẹ ni witiri.
  3. Ṣíṣe fifọ ọwọ mejeeji lofin lẹyin orun oru lẹẹmẹta.