+ -

عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه قَالَ: سَمِعْتُ رَسُولَ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يَقُولُ:
«كُلُّ أُمَّتِي مُعَافًى إِلَّا المُجَاهِرِينَ، وَإِنَّ مِنَ المُجَاهَرَةِ أَنْ يَعْمَلَ الرَّجُلُ بِاللَّيْلِ عَمَلًا، ثُمَّ يُصْبِحَ وَقَدْ سَتَرَهُ اللَّهُ عَلَيْهِ، فَيَقُولَ: يَا فُلاَنُ، عَمِلْتُ البَارِحَةَ كَذَا وَكَذَا، وَقَدْ بَاتَ يَسْتُرُهُ رَبُّهُ، وَيُصْبِحُ يَكْشِفُ سِتْرَ اللَّهِ عَنْهُ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 6069]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ pe:
«Gbogbo ijọ mi ni wọn maa ṣọ kuro nibi aburu ayaafi awọn alaṣehan, ati pe dajudaju ninu aṣehan ni ki ọmọnìyàn o ṣe iṣẹ kan ni oru, lẹyin naa ki o wa ji ti Ọlọhun si ti bo aṣiri rẹ, ki o wa sọ pe: Irẹ lagbaja, mo ṣe nkan bayii bayii ni alẹ ana, ti Ọlọhun si ti bo aṣiri rẹ ni alẹ, yio waa ji lati ṣi gaga aṣiri bibo Ọlọhun kuro».

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 6069]

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju Musulumi ẹlẹṣẹ ni o ṣeeṣe ki o ri amojukuro Ọlọhun ati aforijin Rẹ, ayaafi ẹni ti o ba n fi ẹṣẹ han ní ti ṣiṣe faari ati jijẹ aṣa, oun o lẹtọọ si amojukuro; latari pe yio da ẹṣẹ ni oru, lẹyin naa yio ji ni ẹni ti Ọlọhun ti bo aṣiri rẹ, ni yio ba sọ fun ẹlòmíràn pe oun da ẹṣẹ bayii ni ana, ti o si sun ti Oluwa rẹ ti bo o ni aṣiri, ni yio ba ji ti yoo waa tu aṣiri bibo Ọlọhun lori rẹ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Thai Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Aidaa mimaa fi ẹṣẹ han lẹyin ti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ti bo aṣiri rẹ.
  2. O n bẹ nibi imaa fi ẹṣẹ han titan ibajẹ ka laarin awọn Mumuni.
  3. Ẹni ti Ọlọhun ba bo ni àṣírí ní aye yio bo o ni aṣiri ni ọjọ ikẹyin, ati pe eleyii wa ninu gbigbaaye ikẹ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga pẹlu awọn ẹru Rẹ.
  4. Ẹni ti wọn ba fi ẹṣẹ ṣe adanwo fun ki o bo ara rẹ ni àṣírí ki o si tuba lọ si ọdọ Ọlọhun.
  5. Titobi ẹṣẹ awọn alaṣehan awọn ti wọn mọọmọ maa n fi ẹṣẹ han, ti wọn si maa n pa ara wọn ni adanu amojukuro.