+ -

عَنْ حُذَيْفَةَ رضي الله عنه قَالَ:
كُنْتُ مَعَ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ فَانْتَهَى إِلَى سُبَاطَةِ قَوْمٍ، فَبَالَ قَائِمًا، فَتَنَحَّيْتُ فَقَالَ: «ادْنُهْ» فَدَنَوْتُ حَتَّى قُمْتُ عِنْدَ عَقِبَيْهِ فَتَوَضَّأَ فَمَسَحَ عَلَى خُفَّيْهِ.

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح مسلم: 273]
المزيــد ...

Lati ọdọ Hudhayfah - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe:
Mo wa pẹlu Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ni o wa lọ sibi akitan ijọ kan, ti o si tọ ni iduro, ni mo ba takete si i, o wa sọ pe: «Sunmọ ibi» ni mo ba sunmọ titi mo fi duro si ibi ẹyin gigirisẹ rẹ mejeeji, nigba naa ni o ṣe aluwala ti o si fi ọwọ pa ibọsẹ alawọ rẹ mejeeji.

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Muslim - 273]

Àlàyé

Hudhayfah ọmọ Al-yamān - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- n royin pe oun wa pẹlu Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a-, ni o wa gbero - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - lati tọ, ti o si wọ subāta ijọ kan; oun naa ni aaye ti wọn maa n da idọti ati iyẹpẹ ti wọn ba gba jade ni inu ile si, nigba naa ni o wa tọ ni iduro, èyí tí o si pọ ninu ìṣesí rẹ ni ki o tọ ni ijokoo.
Ni Hudhayfah wa takete si i, ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ fun un pe: Sunmọ ibi, ti Hudhayfah si sunmọ ọn titi ti o fi duro si ẹyin rẹ nibi gigisẹ rẹ mejeeji; ki o le wa gẹgẹ bii gaga fun un ki wọn ma baa ri i ni ìṣesí yẹn.
Lẹyin naa ni o wa ṣe aluwala - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, nigba ti o de ibi fifọ ẹsẹ mejeeji, o fi mọ lórí pipa ibọsẹ alawọ rẹ mejeeji - awọn ni awọ fẹlẹfẹlẹ tabi nkan ti o jọ ọ ti wọn maa n bọ si ẹsẹ ti yio si bo koko ẹsẹ mejeeji - ti ko si bọ wọn silẹ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Dari Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣiṣe lofin pipa ibọsẹ alawọ mejeeji.
  2. Ìní-ẹ̀tọ́ titọ ni iduro pẹlu majẹmu ki nkankan ninu rẹ o ma ta si i lara.
  3. Ṣiṣẹṣa ti Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣa As-Subāto lẹsa - oun naa ni aaye idalẹ ati idọti sí - latari pe ni ọpọ igba o maa rẹlẹ ko si ki n da itọ pada si ara ẹni ti o n tọ.