عَنْ سَعْدِ بْنِ أَبِي وَقَّاصٍ رضي الله عنه عَنْ رَسُولِ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ أَنَّهُ قَالَ:
«مَنْ قَالَ حِينَ يَسْمَعُ الْمُؤَذِّنَ أَشْهَدُ أَنْ لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ وَحْدَهُ لَا شَرِيكَ لَهُ، وَأَنَّ مُحَمَّدًا عَبْدُهُ وَرَسُولُهُ، رَضِيتُ بِاللهِ رَبًّا وَبِمُحَمَّدٍ رَسُولًا، وَبِالْإِسْلَامِ دِينًا، غُفِرَ لَهُ ذَنْبُهُ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 386]
المزيــد ...
Lati ọdọ Sadu ọmọ Abi waqqoosi, ki Ọlọhun yọnu si i, lati ọdọ ojisẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe:
«Ẹni ti o ba sọ nigba ti o n gbọ oluperun pe ash-hadu an laa ilaaha illa Allāhu wahdahu laa sharika laHu, wa anna muhammadan ‘abduHu wa rosuuluhu, rodiitu bil Laahi robban wa bi muhammadin rosuulan wa bil Isilaami diina, wọn a fi ori ẹṣẹ rẹ jin in.
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 386]
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - funni niroo pe dajudaju ẹni ti o ba sọ nigba ti o n gbọ oluperun pe Ash-hadu an laa illaha illā Allāhu wahdahu laa sharika laHu" itumọ rẹ ni: Mo n fi rinlẹ wipe dajudaju ko si ẹni ti ijọsin ododo tọ si ayaafi Ọlọhun, ati pe gbogbo nkan ti wọn n sìn yatọ si i ibajẹ ni in. Wa anna muhammadan ‘abduHu wa rosuuluhu" ìtumọ rẹ ni: Dajudaju ẹru ni wọn o ki n jọsin fun un, ati pe ojiṣẹ ni ti ko ki n parọ, Rodiitu bil Laahi Robban" itumọ rẹ ni: Pẹ̀lú ijẹ Oluwa Rẹ, ati ijẹ Ọlọhun Rẹ, ati awọn orukọ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ, Wa bi muhammadin rosuula" itumọ rẹ ni: Pẹlu gbogbo nkan ti wọn fi ran an, ti o si mu un de etiigbọ wa, wa bil Islam" itumọ rẹ ni: Pẹlu gbogbo awọn ìdájọ́ Isilaamu bii awọn aṣẹ ati awọn nnkan ti wọn kọ̀, "Diinan” itumọ rẹ ni: Ni ti adisọkan ati itẹle, "Gufiro lahu dhanbuhu" itumọ rẹ ni: Awọn ẹṣẹ kekere.