عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه قال: قال رَسُولُ الله صلى الله عليه وسلم:
«إِنَّ اللهَ يَغَارُ، وَإِنَّ الْمُؤْمِنَ يَغَارُ، وَغَيْرَةُ اللهِ أَنْ يَأْتِيَ الْمُؤْمِنُ مَا حَرَّمَ عَلَيْهِ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح مسلم: 2761]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
"Dajudaju Ọlọhun maa n jowu, ati pe dajudaju olugbagbọ naa maa n jowu, owu jijẹ Ọlọhun ni ki olugbagbọ maa ṣe nnkan ti Ọlọhun ṣe ni eewọ fun".
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Muslim - 2761]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju Ọlọhun maa n jowu, O si maa n binu O si maa n korira, gẹgẹ bi olugbagbọ naa ṣe maa n jowu, ti o si maa n binu, ti o si maa n korira, ati pe okunfa jijowu Ọlọhun ni ki olugbagbọ ṣe nnkan ti O ṣe ni eewọ ninu iwa ibajẹ gẹgẹ bii ṣìná ati ki ọkùnrin maa ba ọkùnrin lò pọ̀, ati ole jija ati ọti mimu, ati eyi ti o yàtọ̀ si wọn ninu awọn iwa ibajẹ.