+ -

عَنْ ‌أُبَيِّ بْنِ كَعْبٍ رضي الله عنه قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«يَا أَبَا الْمُنْذِرِ، أَتَدْرِي أَيُّ آيَةٍ مِنْ كِتَابِ اللهِ مَعَكَ أَعْظَمُ؟» قَالَ: قُلْتُ: اللهُ وَرَسُولُهُ أَعْلَمُ. قَالَ: «يَا أَبَا الْمُنْذِرِ، أَتَدْرِي أَيُّ آيَةٍ مِنْ كِتَابِ اللهِ مَعَكَ أَعْظَمُ؟» قَالَ: قُلْتُ: {اللهُ لا إِلَهَ إِلا هُوَ الْحَيُّ الْقَيُّومُ} [البقرة: 255]. قَالَ: فَضَرَبَ فِي صَدْرِي، وَقَالَ: «وَاللهِ لِيَهْنِكَ الْعِلْمُ، أَبَا الْمُنْذِرِ».

[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 810]
المزيــد ...

Lati ọdọ Ubay ọmọ Kahb- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Irẹ Abu Al-Munzir, ǹjẹ́ o mọ aaya wo ninu tira Ọlọhun ti o wa pẹlu rẹ ni o tobi julọ?”, o sọ pe: Mo sọ pé: Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ ni wọn ni imọ julọ. O sọ pe: “Irẹ Abu Al-Munzir, ǹjẹ́ o mọ aaya wo ninu tira Ọlọhun ti o wa pẹlu rẹ ni o tobi julọ?”, o sọ pe: Mo sọ pé: {Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá} [Al-Baqarah: 255]. O sọ pe: O wa fi ọwọ́ lu mi láyà, o wa sọ pé: “Mo fi Ọlọhun búra, o kú oriire imọ naa, ki Ọlọhun ṣe e ni irọrun fun ẹ, irẹ Abu Al-Mundhir”.

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 810]

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- bi Ubay ọmọ Kahb léèrè nipa aaya ti o tobi ju ninu tira Ọlọhun, o wa ṣe iyèméjì nibi dáhùn, lẹ́yìn náà ni o wa sọ pé: Oun ni aayatul Kursiyy: {Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá}, Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ṣe atilẹyin fun un, Anọbi wa lu u ni àyà lati tọka si pe o kún fun imọ ati ọgbọ́n, o wa ṣe adua fun un pe ki o maa dunnu pẹ̀lú imọ yii ki o si rọrùn fún un.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada Ti ede Azerbaijan Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ìwà rere nla ti Ubay ọmọ Kahb, ki Ọlọhun yọnu si i.
  2. Aayatul Kursiyy ni aaya ti o tobi ju ninu tira Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, hiha a ni ẹtọ, ati ìrònú nipa awọn ìtumọ̀ rẹ, ati lilo o.