+ -

عَنْ كَعْبِ بْنِ عُجْرَةَ رضي الله عنه عَنْ رَسُولِ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«مُعَقِّبَاتٌ لَا يَخِيبُ قَائِلُهُنَّ -أَوْ فَاعِلُهُنَّ- دُبُرَ كُلِّ صَلَاةٍ مَكْتُوبَةٍ، ثَلَاثٌ وَثَلَاثُونَ تَسْبِيحَةً، وَثَلَاثٌ وَثَلَاثُونَ تَحْمِيدَةً، وَأَرْبَعٌ وَثَلَاثُونَ تَكْبِيرَةً».

[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 596]
المزيــد ...

Lati ọdọ Ka‘bu ọmọ ‘Ujroh - ki Ọlọhun yọnu si i - lati ọdọ Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe:
«Awọn gbolohun ẹyin irun kan n bẹ ti o ṣe pe ẹni ti o ba sọ wọn - tabi ti o ṣe wọn - ni ẹyin gbogbo irun ọranyan, ko ni mofo, subhānallāh ọgbọn ati mẹta, ati alhamduliLlāhi ọgbọn ati mẹta, ati Allāhu akbar ọgbọn ati mẹẹrin».

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 596]

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - funni niroo nipa awọn iranti ti ẹni ti o ba n sọ ọ o le mofo ti ko si le kabamọ, bi ko ṣe pe ẹsan awọn gbolohun yii a maa bẹ fun un, wọn o si maa wa lẹyin ara wọn, ti wọn o si tun maa sọ wọn lẹyin irun ọranyan, oun naa ni:
"Subhānallāh" ọgbọn ati mẹta, iyẹn ni fifọ Ọ mọ kuro nibi adinku.
Ati "AlhamduliLlāhi" ni igba ọgbọn ati mẹta, ati pe oun ni ìròyìn Ọlọhun pẹlu pipe papọ mọ ninifẹẹ Rẹ ati gbigbe titobi fun Un.
Ati "Allāhu akbar" ni igba ọgbọn ati mẹẹrin, nitori pe Ọlọhun tobi O si gbọnngbọn ju gbogbo nkan lọ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè Czech Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ọla ti n bẹ fun ṣiṣe subhānallāh ati alhamduliLlāhi ati Allāhu Akbar, ati pe awọn ni awọn iṣẹ rere to maa wa titi láéláé.