+ -

عَنْ عَمَّارِ بنِ ياسِرٍ رضي الله عنه قال:
بَعَثَنِي رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ فِي حَاجَةٍ، فَأَجْنَبْتُ فَلَمْ أَجِدِ الْمَاءَ، فَتَمَرَّغْتُ فِي الصَّعِيدِ كَمَا تَمَرَّغُ الدَّابَّةُ ثُمَّ أَتَيْتُ النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، فَذَكَرْتُ ذَلِكَ لَهُ فَقَالَ: «إِنَّمَا كَانَ يَكْفِيكَ أَنْ تَقُولَ بِيَدَيْكَ هَكَذَا» ثُمَّ ضَرَبَ بِيَدَيْهِ الْأَرْضَ ضَرْبَةً وَاحِدَةً، ثُمَّ مَسَحَ الشِّمَالَ عَلَى الْيَمِينِ، وَظَاهِرَ كَفَّيْهِ وَوَجْهَهُ.

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح مسلم: 368]
المزيــد ...

Lati ọdọ Ammār ọmọ Yāsir - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe:
Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ran mi ni iṣẹ kan, ni mo ba ni janaba ti mi o si ri omi, ni mo ba po ara mọ erupẹ gẹgẹ bi ẹranko ṣe maa n po ara mọ ọn, lẹyin naa ni mo wa ba Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ni mo si sọ iyẹn fun un, o si sọ pe: «O ti to fun ẹ ki o fi ọwọ rẹ mejeeji ṣe bayii» lẹyin naa ni o fi ọwọ rẹ mejeeji lu ilẹ ni ẹẹkan, lẹyin naa ni o fi osi pa ọtun, ati ẹyin ọwọ rẹ mejeeji ati oju rẹ».

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Muslim - 368]

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ran Ammār ọmọ Yāsir - ki Ọlọhun yọnu si i - lọ si irin-ajo kan fun awọn bukaata rẹ kan, ni janaba ba ṣẹlẹ si i latara ibalopọ tabi dida atọ pẹlu adun, ti ko si ri omi ti yíò fi wẹ, O jẹ ẹni ti ko mọ idajọ tayammam (Aluwala eleepẹ) fun janaba, amọ o mọ idajọ rẹ fun ẹgbin kekere, Ni o ba gbiyanju ti o si lero pe gẹgẹ bi o ṣe maa fi iyẹpẹ ti o wa ni ori ilẹ pa awọn orike aluwala kan nibi ẹgbin kekere, nitori naa tayammam fun janaba naa gbọdọ ṣẹlẹ pẹlu fifi iyẹpẹ kari gbogbo ara; lati fi ṣe deede omi, ni o ba yi ara mọ iyẹpẹ titi ti o fi kari ara ti o si lọ kirun, Nigba ti o wa ba Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, o sọ iyẹn fun un; ki o le mọ boya o wa loju ọna abi bẹẹkọ? Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa ṣe alaye fun un bi a ṣe n ṣe imọran kuro nibi ẹgbin mejeeji kekere gẹgẹ bii itọ, ati ńlá gẹgẹ bii janaba: Oun naa ni ki o fi ọwọ rẹ mejeeji lu ilẹ ni ẹẹkan, lẹyin naa ki o pa osi lori ọtun, ki o fi pa ẹyin ọwọ rẹ mejeeji ati oju rẹ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Jijẹ dandan wiwa omi siwaju tayammam (Aluwala eleepẹ).
  2. Ṣiṣe tayammam (Aluwala eleepẹ) lofin fun ẹni ti o ni janaba ti ko si ri omi.
  3. Tayammam (Aluwala eleepẹ) fun ẹgbin nla da gẹgẹ bii tayammam fun ẹgbin kekere.
Àlékún