عَنِ ابْنِ عَبَّاسٍ رَضِيَ اللهُ عَنْهُمَا قَالَ:
كَانَ النَّبِيُّ صَلَّى اللهُ عَليهِ وَسَلَّمَ لا يَعْرِفُ فَصْلَ السُّورةِ حَتَّى تَنْزِلَ عَليْهِ {بِسْمِ اللَّهِ الرَّحْمَنِ الرَّحِيمِ}.
[صحيح] - [رواه أبو داود] - [سنن أبي داود: 788]
المزيــد ...
Lati ọdọ Ibnu Abbaas- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- o sọ pe:
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kii mọ gígé àsopọ̀ suura titi ti {BISMILLAAHI RAHMAANI RAHEEM} fi maa sọkalẹ.
[O ni alaafia] - [Abu Daud ni o gba a wa] - [Sunanu ti Abu Daud - 788]
Ibnu Abbaas- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- n ṣàlàyé pe àwọn suura Kuraani Alapọn-ọnle maa n sọ̀kalẹ̀ fun Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ko si nii mọ ibi ti asopọ rẹ ti ge ati òpin rẹ, titi ti “BISMILLAAHI RAHMAANI RAHEEM” fi maa sọ̀kalẹ̀ fun un, igba naa ni o to maa mọ pe suura ti o ṣáájú ti parí, oun si ni ibẹrẹ suura tuntun.